Yoruba
Le yoruba ou yorouba, aussi appelé youriba, yariba ou yooba (autonyme : yorùbá), est une langue d'Afrique de l'Ouest appartenant au groupe des langues yoruboïdes, parmi lesquelles il compte le plus grand nombre de locuteurs. Ce groupe se rattache lui-même à la famille des langues nigéro-congolaises. Les traditions des différentes populations yoruba retracent toutes leurs origines jusqu'à la ville nigériane d'Ile-Ife. Au Nigeria c'est l'une des trois grandes langues du pays avec le haoussa et l'igbo, elle est aussi parlée dans certaines régions du Bénin et du Togo, ainsi qu'aux Antilles et en Amérique latine, notamment à Cuba, par les descendants d'esclaves africains, pratiquant entre autres la Santería (religion syncrétique), et au Brésil, notamment dans le culte du candomblé. Le yoruba est une langue à tons. La langue se subdivise en de nombreux dialectes. Il existe néanmoins aussi une langue standard.
Source : Wikipedia francophone
Èdè Yorùbá Ni èdè tí ó ṣàkójọpọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oò-jíire bí, ní apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní Ìwọ̀-Oòrùn aláwọ̀-dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni Ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ìpínlẹ̀ Èkó, àti Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone,United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ. Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì wuyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ìbátan Kwa ní èdè Yorùbá jé, kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní apá Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Source : Wikipedia local
Article premier de la déclaration universelle des droits de l'homme
Article premier de la Déclaration universelle des droits de l'homme (voir le texte en français) Abala kìíní. Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti ẹ̀tọ́ kọ̀ọ̀kan sì dọ́gba. Wọ́n ní ẹ̀bùn ti làákàyè àti ti ẹ̀rí‐ọkàn, ó sì yẹ kí wọn ó máa hùwà sí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá.
Source : Wikipedia francophone
Alphabets
- alphabet latin
Codes de langue
SOURCE | Code | URL |
---|---|---|
code iso 639-1 de la langue | yo | |
Code iso 639-2 | yor | |
Code iso 639-3 | yor |
Source : Wikidata